Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 25:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Má ṣe di akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí o bá ń pa ọkà.

5. Bí àwọn arákùnrin rẹ bá jọ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan wọn sì kú láìní ọmọkùnrin, opó rẹ̀ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ mìíràn tayọ ẹbí ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni yóò mú u ṣe aya, òun ni yóò sì ṣe ojúṣe ọkọ fún un.

6. Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má baá parẹ́ ní Ísírẹ́lì.

7. Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Ísírẹ́lì. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”

8. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,”

9. opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹṣẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”

10. A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Isírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”

11. Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbéjà ọkọ rẹ̀ kúró lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú.

12. Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe sàánú fún un.

13. Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ: ọ̀kan wíwo àti ọ̀kan fífúyẹ́.

14. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.

15. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 25