Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 25:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe sàánú fún un.

13. Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ: ọ̀kan wíwo àti ọ̀kan fífúyẹ́.

14. Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.

15. O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ.

16. Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.

17. Rántí ohun tí àwọn ará Ámélékì ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.

18. Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

19. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Ámélékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.

Ka pipe ipin Deutarónómì 25