Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 25:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.

2. Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàsán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàsán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

4. Má ṣe di akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí o bá ń pa ọkà.

5. Bí àwọn arákùnrin rẹ bá jọ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan wọn sì kú láìní ọmọkùnrin, opó rẹ̀ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ mìíràn tayọ ẹbí ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni yóò mú u ṣe aya, òun ni yóò sì ṣe ojúṣe ọkọ fún un.

6. Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má baá parẹ́ ní Ísírẹ́lì.

7. Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Ísírẹ́lì. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”

8. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,”

Ka pipe ipin Deutarónómì 25