Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 22:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un.

2. Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un.

3. Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀.

4. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ rẹ̀.

5. Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.

6. Bí o bá se alábàápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jòkòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ.

7. O lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó baà lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.

8. Nígbà tí o bá kọ́ ilé túntún, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má baà mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.

9. Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èṣo oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èṣo ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.

10. Má ṣe fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.

11. Má ṣe wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.

12. Kí o ṣe wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlẹ̀kẹ̀ rẹ.

13. Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, kórìíra rẹ̀,

14. tí o sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo sún mọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé e rẹ̀.”

15. Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ìlú ní ẹnu bodè.

16. Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbààgbà, pé “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀.

17. Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúndíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fí aṣọ hàn níwájú àwọn àgbààgbà ìlú,

Ka pipe ipin Deutarónómì 22