Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:29-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Éṣáù tí ó ń gbé ní Séírì àti àwọn ará Móábù tí ó ń gbé ní Árì, ti gbà wá láàyè títí a fi la Jọ́dánì já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.”

30. Ṣùgbọ́n Ṣíhónì ọba Héṣíbónì kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.

31. Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsí i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”

32. Nígbà tí Síhónì àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jáhásì,

33. Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀.

34. Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátapáta tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí.

35. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa.

36. Láti Áróérì, létí odò Ánónì àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gílíádì, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa.

37. Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jábókù, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2