Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ámónì ń pè wọ́n ní Sámúsúmímù.

21. Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gògòrò bí àwọn ará Ánákì. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ámónì, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

22. Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ Ísọ̀, tí wọ́n ń gbé ní Séírì, nígbà tí ó pa àwọn ará Hórì run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2