Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 18:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀ èdè náà tí ó wà níbẹ̀.

10. Má se jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rúbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ ṣe àyẹ̀wò, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,

11. tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwín gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókúsọ̀rọ̀.

12. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.

13. O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

14. Àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi àyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

15. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrin àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.

16. Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Hórébù ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”

17. Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára.

18. Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrin àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Deutarónómì 18