Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 17:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,

4. tí èyí sì dé etíìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Ísírẹ́lì.

5. Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa.

6. Lẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípaṣẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.

7. Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín.

8. Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ ọ yín tí ó nira jù láti dá: yálà ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù: Ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 17