17. Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bàá yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
18. Nígbà tí ó bá dé orí oyè ilé ọba rẹ̀ kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú un ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì.
19. Èyí gbọdọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ máa kà wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà an rẹ̀ tọkàntọkàn.
20. Kí ó má baà lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yóòkù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sósì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jọba pẹ́ títí ní Ísírẹ́lì.