Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 17:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ṣíwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Éjíbítì láti wá àwọn ẹsin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”

17. Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bàá yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

18. Nígbà tí ó bá dé orí oyè ilé ọba rẹ̀ kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú un ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì.

19. Èyí gbọdọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ máa kà wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà an rẹ̀ tọkàntọkàn.

20. Kí ó má baà lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yóòkù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sósì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jọba pẹ́ títí ní Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Deutarónómì 17