3. Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.
4. Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,
5. àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó
6. Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.
7. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín.
8. Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.
9. Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.
10. Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín.
11. Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
12. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,
13. onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,
14. onírúurú ẹyẹ ìwò,
15. ògòǹgò, òyo, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,
16. onírúurú òwìwí,
17. òwìwí-ọ̀dàn, idì-okùn, ẹyẹ-àkọ̀,