Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 14:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀.

3. Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.

4. Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,

5. àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó

Ka pipe ipin Deutarónómì 14