Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 14:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọ Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí i yín nítorí òkú.

2. Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀.

3. Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.

4. Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,

5. àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó

6. Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.

7. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín.

8. Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 14