Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 13:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Éjíbítì wá kúrò ní oko ẹrú.

11. Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́.

12. Bí ẹ bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé,

13. pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrin yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn sìnà lọ, tí wọ́n wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn,” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀.)

14. Kí ẹ wádìí, ẹ bèèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín.

15. Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá. Ẹ run ún pátapáta, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀.

16. Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárin gbogbo ènìyàn, kí ẹ ṣun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun sísun sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún-un kọ.

17. A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ ọ yín, kí Olúwa ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín.

18. Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí tí ẹ sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 13