Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 12:22-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èṣúó tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́.

23. Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran.

24. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25. Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó báà lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín. Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú Olúwa.

26. Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ síbi tí Olúwa yóò yàn.

27. Ẹ fi ọrẹ síṣun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran.

28. Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́ràn sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o báà dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.

29. Olúwa Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá tí lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn.

30. Lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti pa wọ́n run níwájú u yín, ẹ sọ́ra kí ẹ má baà bọ́ sínú àdánwò nípa bíbéèrè nípa àwọn òrìṣà wọn wí pé, “Báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè yìí ṣe ń sin àwọn òrìṣà wọn? Àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀”

31. Ẹ má ṣe sin Olúwa Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń dáná ṣun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rúbọ sí ère òrìṣà wọn.

32. Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì se yọ kúró níbẹ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 12