Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo.

2. Ẹ rántí lónìí pé kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀;

3. iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárin àwọn ará Éjíbítì: Sí Fáráò ọba Éjíbítì àti gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ̀.

4. Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Éjíbítì, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́sin rẹ̀: bí ó se rì wọ́n sínú òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátapáta títí di òní olónìí yìí.

5. Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní ihà, títí ẹ fi dé ìhín yìí,

6. ohun tí ó ṣe sí Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Ísírẹ́lì tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.

7. Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.

Ka pipe ipin Deutarónómì 11