Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 6:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ọba pàṣẹ pé, kí a mú àwọn alátakò Dáníẹ́lì wá, kí a jù wọ́n sí inú ihò kìnnìún, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀ ihò, kìnnìún lágbára lórí i wọn, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn.

25. Nígbà náà, ni Dáríúsì ọba kọ̀wé sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti gbogbo jákèjádò ilẹ̀ náà:“Kí ire yín máa pọ̀ sí i!

26. “Mo gbé àsẹ kan jáde wí pé: ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì.“Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyèÓ sì wà títí ayé;Ìjọba rẹ̀ kò le è parunìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun

27. Ó ń yọ ni, ó sì ń gba ni là;ó ń ṣe iṣẹ́ àmì àti ìyanuní ọ̀run àti ní ayé.Òun ló gba Dáníẹ́lì làkúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”

28. Dáníẹ́lì sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dáríúsì àti àkókò ìjọba Sáírúsì ti Páṣíà.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 6