Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 6:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó dára lójú Dáríúsì láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba,

2. pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Dáníẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kan nínú un wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára.

3. Dáníẹ́lì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrin àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbérò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba.

4. Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbérò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Dáníẹ́lì lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara.

5. Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”

6. Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dáríúsì ọba, kí o pẹ́!

7. Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún.

8. Nísinsin yìí, ìwọ ọba, gbé òfin yìí jáde, kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé kí a má ba à yí i padà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Médíánì àti Páṣíà, èyí tí kò ní le è parẹ́.”

9. Nígbà náà, ni Dáríúsì ọba fi ọwọ́ sí ìwé àṣẹ náà.

10. Lóòótọ́ Dáníẹ́lì mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó sí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jérúsálẹ́mù sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

11. Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Dáníẹ́lì tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

12. Wọ́n lọ sí iwájú ọba, wọ́n sì rán ọba létí nípa òfin tí ó ṣe pé, “Ìwọ kò ha fi ọwọ́ sí òfin wí pé ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn, láì bá ṣe ìwọ ọba, a ó gbé e jù sínú ihò kìnnìún?”Ọba sì dáhùn pé, “Àṣẹ náà dúró ṣíbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn ará Médíánì àti Páṣíà, èyí tí a kò le è parẹ́.”

13. Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára ìgbékùn Júdà, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”

14. Nígbà tí ọba gbọ́ èyí, inú un rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi; ó pinnu láti kó Dáníẹ́lì yọ, títí òòrùn fi rọ̀, ó sa gbogbo ipá a rẹ̀ láti gba Dáníẹ́lì sílẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 6