Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 2:20-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Dáníẹ́lì wí pé:“Ọpẹ́ ni fún orúkọ Olúwa láé àti láéláé;tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára

21. Ó yí ìgbà àti àkókò padà;ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́nàti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

22. Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àsírí hàn;ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùnàti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà

23. Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbáraó ti fi àwọn nǹkan tí a bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún minítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

24. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì títọ́ Áríókù lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run, Dáníẹ́lì wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Bábílónì run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sí sọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25. Lẹ́ṣẹ̀kan náà, Áríókù yára mú Dáníẹ́lì lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Júdà, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”

26. Ọba béèrè lọ́wọ́ ọ Dáníẹ́lì ẹni tí a tún ń pè ní Beliteṣáṣárì pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”

27. Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àsírí tí ọba béèrè fún

28. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àsírí hàn. Ó ti fi han ọba Nebukadinéṣárì, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

29. “Ọba, bí ìwọ ṣe ṣùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àsírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

30. Ṣùgbn fún èmi, a fi àsírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.

31. “Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú ù rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ.

32. Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ ọ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ,

33. àwọn ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apákan irin àti apákan amọ̀.

34. Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹṣẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́.

35. Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́ṣẹ̀ kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láì ṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.

36. “Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

37. Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ;

38. ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko ìgbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí i wúrà náà.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 2