Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹta Sárúsì ọba Páṣíà, a fi ìran kan hàn Dáníẹ́lì (ẹni tí à ń pè ní Bélítésásárì). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.

2. Ní àsìkò náà, èmi Dáníẹ́lì ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.

3. Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.

4. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tígírísì,

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 10