Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.