Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 62:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmitítí tí yóò fi fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀tí yóò sì fi òun ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.

8. Olúwa ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀àti nípa agbára apá rẹ:“Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹdi oúnjẹ fún ọ̀tá rẹbẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnìtuntun rẹ mọ́èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;

9. ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́tí wọn ó sì yin Olúwa,àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú unnínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”

10. Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó!Ẹ sa òkúta kúròẸ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè

11. Olúwa ti ṣe ìkédetítí dé òpin ilẹ̀ ayé:“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé,‘kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀,àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”

12. A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,ẹni ìràpadà Olúwa;a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 62