Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún tí ọba Hùṣáyà kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ḿpìlì.

2. Àwọn Ṣéráfù wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹṣẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.

3. Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ ogungbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

4. Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹ́ḿpìlì sì kún fún èéfín.

5. “Ègbé ni fún mi!” Ni mo ké, “Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

6. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ.

7. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wòó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 6