Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 45:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,sí Kírúsì, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì múláti dojú àwọn orílẹ̀ èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,láti sí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.

2. Èmi yóò lọ ṣíwájú rẹèmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹṣẹÈmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹèmi ó sì gé ọ̀pá irin.

3. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó farasin,Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

4. Nítorí Jákọ́bù ìránṣẹ́ miàti Ísírẹ́lì ẹni tí mo yànMo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lóríbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 45