Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 42:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ta ni nínú un yín tí yóò tẹ́tí sí èyítàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?

24. Ta ni ó fi Jákọ́bù lélẹ̀ fún ìkógun,àti Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?Kì í há ṣe Olúwa ni,ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

25. Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,rògbòdìyàn ogun.Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀èdè kò yé wọn;ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 42