Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ohùn kan wí pé, “Kígbe ṣókè.”Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná inú un pápá.

7. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.

8. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

9. Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Ṣíhónì,lọ sí orí òkè gíga.Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù,gbé ohùn rẹ ṣókè pẹ̀lú ariwo,gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlúu Júdà,“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

10. Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jọba fún un.Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

11. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 40