Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?

13. Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14. Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹàti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́ntàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?

Ka pipe ipin Àìsáyà 40