Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ tùú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,ni Ọlọ́run yín wí.

2. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jérúsálẹ́mùkí o sì kéde fún unpé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,pé à ti san gbésè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwaìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

3. Ohùn ẹnìkan tí ń pè:“Nínú ihà ẹ pèṣèọ̀nà sílẹ̀ fún Olúwa:ṣe é kí ó tọ́ ní ihàòpópónà fún Ọlọ́run wa.

4. Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé ṣókè,gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àtiọ̀nà pálapàla ni a yóò sọ di títẹ́jú pẹrẹṣẹ,

5. Ògo Olúwa yóò sì di mímọ̀gbogbo ọmọnìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rii.Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

6. Ohùn kan wí pé, “Kígbe ṣókè.”Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná inú un pápá.

7. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.

8. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

9. Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Ṣíhónì,lọ sí orí òkè gíga.Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù,gbé ohùn rẹ ṣókè pẹ̀lú ariwo,gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlúu Júdà,“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

10. Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jọba fún un.Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

11. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́.

12. Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?

13. Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

Ka pipe ipin Àìsáyà 40