Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 3:18-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

19. gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,

20. gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,

21. òrùka ọwọ́ àti ti imú,

22. àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,

23. Díńgí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

24. Dípò òórùn dídùn, òórún búbubú ni yóò wá,okùn ni yóò wà dípò àmùrè,orí pípá ni yóò dípò ìrun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.

25. Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.

26. Àwọn bodè Síònì yóò sunkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 3