Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 26:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa, ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókèṣùgbọ́n àwọn kò rí i.Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹkí ojú kí ó tì wọ́n;jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọnọ̀ta rẹ jó wọn run.

12. Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ nió ṣe é fún wa.

13. Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìírànlẹ́yìn rẹ ti jọba lé wa lórí,ṣùgbọ́n orúkọọ̀ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.

14. Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́;gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta.

15. Ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè gbòòrò, Olúwa;ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè bí sí i.Ìwọ ti gba ògo fún araàrẹ;ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ ṣẹ́yìn.

16. Olúwa, Wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njúu wọn;nígbà tí o jẹwọ́n ní ìyà,wọ́n tilẹ̀ fẹ́ ẹ̀ má le gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 26