1. Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Júdà:Àwa ní ìlú alágbára kan,Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣeògiri àti ààbò rẹ̀.
2. Ṣí àwọn ìlẹ̀kùnkí àwọn olódodo orílẹ̀ èdè kí ó lè wọlé,orílẹ̀ èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
3. Ìwọ yóò paámọ́ ní àlàáfíà pípéọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,nítorí Olúwa, Olúwa ni àpátaayérayé náà.
5. Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹṣẹó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6. Ẹṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ẹṣẹ̀ aninilára n nì,ipaṣẹ̀ àwọn òtòsì.
7. Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́júÌwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nààwọn olódodo kúnná.
8. Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹàwa dúró dè ọ́;orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹàwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayéàwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.