Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 23:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ta ló gbérò èyí sí Tírè,ìlú aládé,àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládétí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míkání orílẹ̀ ayé?

9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ baàti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́láilé ayé sílẹ̀.

10. Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò Náì,Ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì,nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.

11. Olúwa ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkunó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíàpé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

12. Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí!“Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì,níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”

13. Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì,àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìíÀwọn Ásíríà ti sọ ọ́ diibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà;wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè,wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhòwọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

14. Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì;wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15. Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16. “Mú hápù kan, rìn kọjá láàrin ìlú,Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;lu hápù rẹ dáadáa, kọ ọ̀pọ̀ orin,kí a lè ba à rántíi rẹ.”

17. Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tírè jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.

18. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èree rẹ̀ àti owó iṣẹ́ẹ rẹ̀ ni a ó yà ṣọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 23