Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 21:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,àwọn agun-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tàbí àwọn tí ó gun ràkúnmí,jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,àní ìmúra gidigidi.”

8. Báyìí ni alóre náà kígbe,“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, Olúwa mi, mo dúró ní ilé ìṣọ́,alaalẹ́ ni mo fi ń wà nípò mi.

9. Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìínínú kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.Ó sì mú ìdáhùn padà wá:‘Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú!Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ló fọ́nká lórí ilẹ̀!’”

10. Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,mo sọ ohun tí mo ti gbọ́láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

11. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dúmáhì:Ẹnìkan ké sí mi láti Séírì wá“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”

12. Alóre náà dáhùn wí pé,“Òwúrọ̀ súnmọ́tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrèkí o sì tún dẹ̀yìn padà wá.”

13. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Arábíyà:Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dídánítì,tí ó pàgọ́ sínú igbó Arábíyà,

14. gbé omi wá fún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ;ẹ̀yin tí ó ń gbé Tẹ́mà,gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.

15. Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,kúrò lọ́wọ́ ọrun tí ó lòàti kúrò nínú ìgbóná ogun.

16. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrin ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ayẹkẹ Kédárì yóò wá sí òpin.

17. Àwọn tafàtafà tí ó ṣálà, àwọn jagunjagun Kédárì kò ní tó nǹkan” Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó ti sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 21