Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 21:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. gbé omi wá fún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ;ẹ̀yin tí ó ń gbé Tẹ́mà,gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.

15. Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,kúrò lọ́wọ́ ọrun tí ó lòàti kúrò nínú ìgbóná ogun.

16. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrin ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ayẹkẹ Kédárì yóò wá sí òpin.

17. Àwọn tafàtafà tí ó ṣálà, àwọn jagunjagun Kédárì kò ní tó nǹkan” Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó ti sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 21