Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 21:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan ihà lẹ́bàá òkun:Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní ilẹ̀ ní gúṣù,akógunjàlú kan wá láti ihà,láti ilẹ̀ ìpayà.

2. Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fi hàn míọlọ̀tẹ̀ ti tasírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.Élámù kojújà! Mẹ́díà ti tẹ̀gùn!Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin,ni ó búra.

3. Pẹ̀lú èyí, ìrora kómi lára gírígírí,ìrora gbámimú, gẹ́gẹ́ bí i tiobìnrin tí ń rọbí,Mo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,ọkàn mi pòrúúrù nípa ohun tí mo rí.

4. Ọkàn mí dàrú,ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,tanmọóko tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ ríti wá di ìpayà fún mi.

5. Wọ́n tẹ́ tábìlì,wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,wọ́n jẹ, wọ́n mu!Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin òṣìṣẹ́,ẹ kún aṣà yín!

6. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Lọ, kí o bojúwòdekí o sì jẹ́ kí ó wá sọ ohun tí ó rí.

7. Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,àwọn agun-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tàbí àwọn tí ó gun ràkúnmí,jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,àní ìmúra gidigidi.”

8. Báyìí ni alóre náà kígbe,“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, Olúwa mi, mo dúró ní ilé ìṣọ́,alaalẹ́ ni mo fi ń wà nípò mi.

9. Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìínínú kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.Ó sì mú ìdáhùn padà wá:‘Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú!Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ló fọ́nká lórí ilẹ̀!’”

10. Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,mo sọ ohun tí mo ti gbọ́láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

11. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dúmáhì:Ẹnìkan ké sí mi láti Séírì wá“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”

Ka pipe ipin Àìsáyà 21