Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 19:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àyasí omi yóò máa rùn;àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkùwọn yóò sì gbẹ.Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7. àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú,tí ó wà ní oríṣun odò Náì.Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náìyóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànùtí kò sì ní sí mọ́.

8. Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò,gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí;yóò sì máa rùn.

9. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminúàwọn ahunsọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìṣàn ọkàn yóò ṣe.

11. Àwọn oníṣẹ́ Ṣóánì ti di aláìgbọ́n,àwọn ọlọgbọ́n olùdámọ̀ràn Fáráòń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.Báwo ló ṣe lè sọ fún Fáráò pé,“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba ijọ́un.”

12. Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?Jẹ́ kí wọn fi hàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mímọ̀ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogunti pinnu lórí Éjíbítì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 19