Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 19:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,gbogbo ilẹ̀ odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.

6. Àyasí omi yóò máa rùn;àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkùwọn yóò sì gbẹ.Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7. àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú,tí ó wà ní oríṣun odò Náì.Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náìyóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànùtí kò sì ní sí mọ́.

8. Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò,gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí;yóò sì máa rùn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 19