Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 14:26-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.

27. Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

28. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Áhásì kú:

29. Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì,pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀yóò ti hù jáde,èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni.

30. Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.Ṣùgbọ́n gbòǹgbòo rẹ ni èmi ó fi ìyàn parun,yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

31. Kígbe, Ìwọ ẹnu ọ̀nà! Pariwo, Ìwọ ìlú!Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì!Kurukuru èéfín kan ti Àríwá wá,kò sì sí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

32. Kí ni ìdáhùn tí a ó fúnagbẹnusọ orílẹ̀ èdè náà?“Olúwa ti fi ìdí Ṣíhónì kalẹ̀,àti nínú un rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tía ti pọ́nlójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 14