Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 14:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

17. Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”

18. Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.

19. Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojìgẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀,àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,àwọn tí idà ti gún,àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,

20. A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn,nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.Ìran àwọn ìkàni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.

21. Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńláa wọn,wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlúu wọn.

22. “Èmi yóò dìde ṣókè sí wọn,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti àwọn tí ó sálà,àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”ni Olúwa wí.

23. “Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwíàti sí irà;Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

24. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.

25. Èmi yóò run Ásíríà ní ilẹ̀ mi,ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìkáa wọn.”

26. Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.

27. Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

Ka pipe ipin Àìsáyà 14