Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 14:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá,ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayéÌwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí!

13. Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọní ṣónṣó orí òkè mímọ́.

14. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

17. Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”

18. Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.

19. Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojìgẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀,àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,àwọn tí idà ti gún,àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,

20. A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn,nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.Ìran àwọn ìkàni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.

21. Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńláa wọn,wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlúu wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 14