Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 13:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.

8. Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,ìrora àti ìpayínkeke yóò dì wọ́n mú,wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.Ẹnìkín-ín-ní yóò wo ẹnìkejìi rẹ̀ pẹ̀lú ìpayàojú wọn á sìgbinájẹ.

9. Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínúàti ìrunú gbígbóná—láti sọ ilẹ̀ náà dahoroàti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú un rẹ̀ run.

10. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run ati ìkójọpọ̀ wọnkò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ òòrùn yóò di òkùnkùnàti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.

11. Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn.Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéragaèmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.

12. Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọnju ojúlówóo wúrà lọ,yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà ófírì lọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 13