Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 13:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Bábílónì, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọbaògo ìgbéraga àwọn ará Bábílónìni Ọlọ́run yóò dojúrẹ̀ bolẹ̀gẹ́gẹ́ bí Sódómù àti Gòmórà.

20. A kì yóò sì gbé ibẹ̀ mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;Árábù kan yóò fi àgọ́ rẹ lélẹ̀ níbẹ̀,Olùsọ́ àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n àwọn ohun abẹ̀mí aṣálẹ̀ ni yóò gbé bẹ̀,àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,níbẹ̀ ni àwọn òwììwí yóò máa gbéníbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́-igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.

22. Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 13