Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èhíhù kan yóò sọ láti ibikùkùté Jéésè,láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kanyóò ti so èso.

2. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé eẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òyeẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbáraẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa

3. Òun yóò sì ní inúdídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojúu rẹ̀ rí,tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etíi rẹ̀ gbọ́,

4. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnufún àwọn aláìní ayé.Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

5. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká.

6. Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìúnàti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

7. Màlúù àti béárì yóò máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,kìnnìún yóò sì máa jẹ koríkogẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.

Ka pipe ipin Àìsáyà 11