Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 10:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Wọ́n wọ Áíyátì,Wọ́n gba Mígírónì kọjáWọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mísímásì.

29. Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,“Àwa ó tẹ̀dó sí Gébà lóru yìí.”Rámà mì tìtìGíbíà ti Ṣọ́ọ̀lù sá lọ.

30. Kígbe ṣókè, ìwọ ọmọbìnrin GálímùDẹtísílẹ̀, Ìwọ LáíṣàÒpè Ánátótì.

31. Mádíménà ti fẹṣẹ̀ fẹ́ ẹÀwọn ènìyàn Gébímù ti farapamọ́.

32. Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nóbùwọn yóò kan sáárá,ní òkè ọmọbìnrin Ṣíhónìní òkè Jérúsálẹ́mù.

33. Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀Àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.

34. Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,Lẹ́bánónì yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 10