Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Ṣọ́ọ̀lù kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jónátanì.

2. Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Síbà, Wọ́n sì pèé wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Síbà bí?”Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”

3. Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ṣíbẹ̀, kí èmi ṣe ooré Ọlọ́run fún un?”Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Jónátanì ní ọmọ kan ṣíbẹ̀ tó ya arọ.”

4. Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?”Síbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Mákírì, ọmọ Ámíélì, ní Lódébárì.”

5. Dáfídì ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Mákírì ọmọ Ámíélì láti Lódébárì wá.

6. Méfibóṣétì ọmọ Jónátaanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì tọ Dáfídì wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un.Dáfídì sì wí pé, “Méfibóṣétì!”Òun sì dáhún wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 9