Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 7:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Nátánì wá pé:

5. “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dáfídì, pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.

6. Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè ti ilẹ̀ Éjíbítì wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi.

7. Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Ísírẹ́lì, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kédárì kọ́ ilé fún mi.” ’

8. “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dáfídì pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì.

9. Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sáà gé gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé.

10. Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó ti wọn, wọn kì yóò sì ṣípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́.

11. Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ:

12. Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ijọba rẹ kalẹ̀.

13. Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.

14. Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.

15. Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ.

16. A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 7