Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 7:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nǹkan kékeré ni èyí sáà jásí lójú rẹ, Olúwa Ọlọ́run; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí há ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Ọlọ́run?

20. “Àti kín ní ó tún kù tí Dáfídì ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Ọlọ́run mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.

21. Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.

22. “Ìwọ sì tóbi, Olúwa Ọlọ́run: kò sì sí ẹni tí ó dà bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́.

23. Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì, àwọn tí Ọlọ́run lọ ràpadà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Éjíbítì wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn.

24. Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn.

25. “Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí.

26. Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Ísírẹ́lì!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.

27. “Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogún, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ.

28. Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ jèẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ.

29. Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ: nítorí ìwọ, Olúwa Ọlọ́run, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípaṣẹ̀ ìbùkún rẹ.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 7