Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 6:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ibínú Olúwa sì ru sí Úsà; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.

8. Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.

9. Dáfídì sì bẹ̀rù Olúwa ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí-ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”

10. Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì; ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì.

11. Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.

12. A sì rò fún Dáfídì ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀.

13. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.

14. Dáfídì sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dáfídì sì wọ éfódù ọ̀gbọ̀.

15. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.

16. Bí àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dáfídì wá; Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

17. Wọ́n sì mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrin àgọ́ náà tí Dáfídì pa fún un: Dáfídì sì rubọ́ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa.

18. Dáfídì sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

19. Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti èkìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

20. Dáfídì sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti wá pàdé Dáfídì, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Ísírẹ́lì ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 6