Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 6:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù wá, èyí tí ó wà ní Gíbéà: Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.

4. Wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù jáde wá, tí ó wà ní Gíbéà, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Áhíò sì ń rìn níwájú àpótí-ẹ̀rí náà.

5. Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurúu èlò orin àti ìlù háàpù, ní ara tanborí, sisitirumù àti kíńbálì.

6. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dì í mú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.

7. Ibínú Olúwa sì ru sí Úsà; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.

8. Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.

9. Dáfídì sì bẹ̀rù Olúwa ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí-ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”

10. Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì; ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì.

11. Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.

12. A sì rò fún Dáfídì ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀.

13. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 6