Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 6:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti èkìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

20. Dáfídì sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti wá pàdé Dáfídì, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Ísírẹ́lì ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

21. Dáfídì sì wí fún Míkálì pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Ísírẹ́lì, èmi ó sì ṣúre níwájú Olúwa.

22. Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìnìyín lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”

23. Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀ òdì yìí sí Dáfídì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 6